Tiwalasa : PÀTÀKÌ ÉDÉ ABÍNÍBÍ

Olóòtú- Olúsọlá Adìgún àti Tèmítọ́pé Fálàáná

Akọle- pàtàkì èdè abínibí ní ìlè yorùbá

Èdè se pàtàkì pupọ jù kaakiri àgbáńlá aye nítorí pé èdè ni ọmọ ẹ̀nìyàn maa n lo làti sisọ ero ọkan wọn  jade lati ẹnu ènìkàn sí ẹlomiiran. ṣíṣe amunlo èdè ni o n jẹ ki ìbágbé pò àwọn ènìyàn o rọrunlaarin awujo wa gbogbo. Olúkúlùkù orílẹ̀ èdè,ipinle, ìlú ati ẹya agbegbe kọọkan ni won ni èdè ti wọn sọ lati le jẹ kí ìgbọ́ra ẹniye o wa nínú ibagbe pọ wọn. Èdè wa ni ọlokan-o-jọkan, bakan naa si ni èdè kan yàtò si òmíràn.

Èdè maa n dàgbà, o si maa n yi padà láti ìgbà dé ìgbà. Bẹẹ naa sì ni èdè lee ku pátápátá ti àwọn ènìyàn ko ba maa loo tàbí sọ ọ mọ.

Ìran yorùbá ni èdè tí wọn n sọ ti o yatọ gédé ńgbé si ti iran tàbì ẹ̀yà mìíran tí kìí se ọmọ kò-o-ótu- oòjìíre lati ìgbà ìwásẹ̀ ni igbọra ẹniye ti wa láárín àwọn ìran yorùbá nípasè ṣíṣe àmúlò Yorùbá ajumọlo ti o jẹ  olórí ẹka èdè ìran yorùbá.Fífọ́n káà kìrì ti ìran yorùbá fọn káà kiri ko nì ki ẹya kọọkan o ma gbọ ara wọn ye.

Fun ìdí eyi,ede ti ìran tabi ẹya yorùbá n sọ jade ti agbọye si wa láárín wọn yatọ si èdè adugbo tabi ẹya kóówá ni a n pe ni ‘’Ede yorùbá’’ ti o jẹ ti ‘’Abínìbí Yorùbá’’’.

Èdè abìnìbì yorùbá yìì ni èdè akọkọ ti ọmọ yoo maa gbọ lati ẹnu ìyá ati bàbá rẹ. Oun ni ọmọ yoo kọkọ fi la ohun. Ni wọn fi maa n sọ pé ti ọmọ yoo ba la ohun, igbẹ baba ni fi n bọnu.

Èdè abìnìbì ẹni ni o yẹ ki a gbọ daada ju. Nitoripe oun ni a o fi maa ronú jinle ki a tó yii paada si èdè miiran ti o jẹ èdè àkọ́kún tẹni. Sugbọn ni ode òni, ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ obí ni kii sọ èdè abìnìbì ti o jẹ ti yorùbá fun awọn ọmọ wọn ni ile.Koda, ti ọmọ ba see si sọ èdè abìnìbì si awọn obi rẹ ni ile, wọn yoo tun maa sọ pe “Don’t speak varnacular”. Wọn yoo pa ni dandan fun awọn ọmọ wọn lati maa sọ èdè gẹẹsi [English language] ninu ile. Ti awọn ọmọ ba tun de ile ẹkọ, wọn ko tun ni anfaani lati sọ èdè abìnìbì wọn ti o jẹ èdè yorùbá .koda,wọn yoo san owo ìtantàn[Fine] ti wọn ba see si sọ èdè wọn ni ile ẹkọ.

Eyi ni ko jẹ ki ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ọmọ o gbọ èdè  abìnìbì wọn daadaa mọ,ti yoo si maa sọ èdè yorùdá ti ko bojumu laarin awùjọ́.Ohun ti ko ye ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ eniyan ni pe èdè yorùbá ti abìnìbì wa kìí se ‘’Varnacular’’ o.Ti ẹba mo itumọ ‘’Varnacular’’ ninu ìwé atúmọ̀[Dictionary] wọn yoo rii pe èdè yorùbá ko si lara èdè ti a le to mọ ‘’Varnacular language’’[The language spoken by uncivilised people in a particular area or by a particular group,especially one that is not the official or written language].           ọgọọrọ ọmọ yorùbá ni ojú maa n ti lati ka ede wọn laarin awujọ ti o si je pe edeelẹ́dẹ́ ni wọn a ka si bàbàrà.

Eyi ti gbogbo wa o fura si,ohun ti a ko si kiyesi ni wipe awọn oyinbo alawo funfun tin kẹkọkọ gboye lori èdè yorùbà awọn ojogon n fòju inu wo wi pe pẹlu ọwọ yorùbà fi n mì ẹde.

 

TIWALASA -EDE ABIMBI

TIWALASA – ISE ABIMBI